MO TUN TI DE OLODUMARE


MO TUN TI DE OLODUMARE
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 09/02/2017

Egbe: Mo tun ti de Olodumare
Mo tun de l’oni mo wa gba’re t’emi
Baba ma je ki emi lo l’ofo
Mo tun ti de o mo wa gba’re Oluwa.

  1. Nigbati Mose de okun pupa
    T’awon omo Israeli fe so ni okuta pa
    Iwo l’O dahun, t’O p’okun niya
    Wa da mi l’ohun mo fe gba’re Oluwa.

  2. Nigbati Hana nsokun ni Shilo
    Ti awon eniyan l’ero pe se l’o munti yo
    Iwo l’O dahun t’O si fun l’omo
    Wa da mi l’ohun mo fe gba’re Oluwa.

  3. ‘Gbati Jabesi omo ‘banuje
    Gbadura pe ki O wa yi igba ohun pada
    Iwo l’O dahun t’O si bukun fun
    Wa da mi l’ohun mo fe gba’re Oluwa.

  4. Gba Modikai gbadura si O
    ‘Tori Hamani pinu l’ati gbe ko s’ori’gi
    Iwo l’O dahun t’O s’ohun titun
    Wa da mi l’ohun mo fe gba’re Oluwa.

  5. Gba Jona ba’ra re ninu eja
    Ti o si dabi enipe ko si ireti mo
    Ni’gba t’O dahun l’eja po s’oke
    Wa da mi l’ohun mo fe gba’re Oluwa.

  6. ‘Gbati Josefu fee ko Maria
    Nitori ko mo bi oyun Jesu se de’nu re
    Iwo l’O dahun t’O yanju oro.
    Wa da mi l’ohun mo fe gba’re Oluwa.

  7. Ole ti a kan mo agbelebu
    Nigba ti o ku die ko wo orun apadi
    Iwo l’O dahun t’O mu lo s’orun
    Wa da mi l’ohun mo fe gba’re Oluwa.