JESU O TOBI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date:16/3/2016
Jesu alagbara
Gbogbo Woli igbaani
Ninu Majemu mejeeji
Mo O ni Olorun.
Egbe: Jesu O tobi (O tobi)
Iyanu ni O (iyanu)
Jesu O ko l’afiwe
Ko s’Oluwa bii Re.
K’a to bi O s’aye
O be Abrahamu wo
Jakobu ati Joshua
Ati awon miran.
Wundia l’o bi O
O f’oye y’awonojogbon
O si ya Maria l’enu
Ko si omo biiRe.
Ni odo Jodani
Johanu f’ogo fun O
Emi Mimo si ba le O
Iwo l’O ga julo.
Satani dan O wo
O ko s’asise kan kan
Igbe aye Re je mimo
Ti o wu Olorun.
O le Esu jade
Ikoni Re ko l’egbe
O segun awon asodi
O ko ni’gbakeji.
O rin l’ori okun
O wo alaisan san
O ji awon oku dide
O m’iji dake je.
O ku, O si jinde
O goke lo si orun
Oo tun pada wa l’ojo kan
Oo se’dajo aye.
Iwo l’Oba l’orun
Iwo l’Oluwa l’aye
Iwo ni O ni aye mi
Iwo l’Olorun mi.
Mo f’aye mi fun O
Uno jere okan fun O
Emi yo ba O pada lo
Si ile Re l’orun.