HYMN – WA BAMI SORO

WA BA MI S’ORO

  1. Wa ba mi s’oro, l’oni Oluwa
    Mo nilo idari Re, ‘gba gbogbo
    S’oro s’emi mi, t’okan, t’ara mi
    Je k’Emi Mimo, ba mi s’oro.

Egbe:
Baba ba mi soro, k’Esu ma baa tan mi
Baba ba mi soro, k’aye mi le roju
Baba ba mi soro, k’emi le ri, b’o ti ye ki nri
Su-gbon ti O ba ba mi s’oro yo dara fun mi
‘Torina ba mi s’oro, ba mi s’oro
Jesu mi wa ba mi s’oro bayi
Je k’emi gb’ohun Re.

  1. Tun ba mi s’oro, b’O ti se tele
    Ki nto ronupiwada, d’atunbi
    B’O ti tu asi-ri, Esu fun mi
    Fi ‘fe Re han mi, ba mi s’oro.
  2. O tun aye se, nipa siso pe
    Je ki imole k’owa, o ri be
    Iye l’oro Re, o si l’agbara
    L’ati tun mi mo, ba mi so ro.

  3. Adamu ti o, lo s’inu ese
    T’ori anu Re l’O se, ba s’oro
    O tun se’leri, Olugbala fun
    F’okan mi bale, ba mi s’oro.

  4. Ni’gba Bibeli, O b’opo s’oro
    Noah, Abrahamu a-ti Mose
    Oro Re l’O fi, tun aye won se
    Tun aye mi se, ba mi s’oro.

  5. O ran oro Re, si won ni’gbani
    O se ‘wosan arun won, at’aisan
    S’oro iye Re, wo mi san l’oni
    Fun mi ni’lera, ba mi s’oro.

  6. Opo ti omo, re ku ni Naini
    O p’ase fun pe ko ma, se so’kun
    So fun ‘banuje, ko fi mi sile
    Tan isoro mi, ba mi s’oro.

  7. Awon ti Emi, Mimo Re ndari
    Awon ni omo Olo-run tooto
    Je ki Emi Re, maa to’sise mi
    Ma je ki nsubu, ba mi soro.

  8. B’O ti pase fun, Lasaru t’o ku
    K’o jade kuro ninu, iboji
    Pase fun ire, k’o wa s’aye mi
    L’ati bukun mi, ba mi s’oro.

  9. Bibeli Mimo, ti O fi fun wa
    Iranwo Re l’o le mu, k’o ye wa
    Mu mi gb’ohun Re, ninu Bibeli
    Fi’we Re ye mi, ba mi s’oro.

  10. B’o ti ni k’O s’o-kuta d’akara
    Esu ko siwo l’ati, dan mi wo
    B’O s’oro si mi, un o segun re
    Fun mi l’ogbon Re, ba mi s’oro.

  11. T’a ba de orun, ‘wo yo so fun wa
    Omo’do rere wonu, ayo mi
    Je k’emi pelu, ni’pin ninu Re
    K’ojo naa to de, ba mi s’oro.

Z. A. Ogunsanya, 25/3/206.