TEWO GB’OPE MI BABA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 19/4/2018. 180416-7 At the
beginning of Yoruba Bible study.
- Tewo gb’ope mi baba
Gba iyin Re ti mo mu wa o
Iwo nikan ma l’ope ye fun
T’ewo gb’ope mi o baba.
Egbe: Baba E se, mo dupe o
T’ewo gb’ope mi o baba.
-
Iwo l’ope ye Baba
Iwo nikan ma l’ogo ye o
Ore Re ma po nin’aye mi
T’ewo gb’ope mi o baba. -
Mo f’ogo fun O Baba
Mo f’iyin fun oruko Re o
Iru Re ko si n’ibi kankan
T’ewo gb’ope mi o baba. -
O gb’okan mi la Baba
O fun mi ni iwenumo Re
Ati agbara Emi Mimo
T’ewo gb’ope mi o baba. -
L’osan at’oru Baba
N’ile, l’oko at’ibi gbogbo
Abo Re daju ni aye mi
T’ewo gb’ope mi o baba. -
Jije, mimu mi Baba
Nina, lilo mi n’igba gbogbo
Iwo nikan ni mo gb’oju le
T’ewo gb’ope mi o baba. -
L’ana, l’oni mi Baba
L’ola ati ni ayeraye
Iwo nikan n’igbekele mi
T’ewo gb’ope mi o baba.