SE IYANU OLU ORUN SE IYANU FUN WA
Composed by Z. A. OGunsnaya, 10/10/2019.
Egbe: Se iyanu, Olu Orun se iyanu fun wa
Se iyanu, Baba wa tun se iyanu fun wa
Odo Re nikan, l’ati le ri iyanu otito (gba o Baba)
Se iyanu, Baba wa tun se iyanu fun wa.
1. Iyanu ti E se ni ijosi, ti E fi pin okun pupa niya
Iyanu ti E se ni ijosi, ti E fi so Mara d’omi didun
E tun wa se iyanu fun wa o (Baba), ki ona wa k’o la kedere.
2. Iyanu ti E se ni ijosi, ti Jodani fi gbe fun Israeli
Iyanu ti E se ni ijosi, ti odi Jeriko fi wo lule
E tun wa se iyanu fun wa o (Baba), ki idena kuro l’ona wa.
3. Iyanu ti E se ni ijosi, ti E fi ran Mana lati orun
Iyanu ti E se ni ijosi, t’omi fi jade ninu apata
E tun wa se iyanu fun wa o (Baba), ki ipese Re le je tiwa.
4. Iyanu ti E se ni ijosi, ti Dafidi fi pa Goliati
Iyanu ti E se ni ijosi, ti Joshua fi segun Kenani
E tun wa se iyanu fun wa o (Baba), ki ota ma se le bori wa.
5. Iyanu ti E se ni ijosi, ti Ana fi di iya olomo
Iyanu ti E se ni ijosi, ti Solomoni fi di olowo
E tun wa se iyanu fun wa o (Baba), ki ibukun Re le je tiwa.
6. Iyanu ti E se ni ijosi, ti Peteru fi rin l’ori okun
Iyanu ti E se ni ijosi, t’o mu ki Paulu ji oku dide
E tun wa se iyanu fun wa o (Baba), ki Esu k’o teriba fun wa.
7. Iyanu ti E se ni ijosi, ti E fi so wa d’omo igbala
Iyanu ti E se ni ijosi, ti E fi ko gbogbo arun wa lo
E tun wa se iyanu fun wa o (Baba), ki aye wa se aseyori.