OWO NI FUN ORUKO RE.
- Owo ni fun oruko Re
Olorun Olodumare
Titi aye la o ma yin O
Iwo nikan ni Olorun
L’aye ati l’orun.
Egbe: Baba wa ti nbe l’orun
Ko si oba t’o da bi Re
Awa ise owo Re Baba
L’o ye k’a jumo ma yin O
L’aye ati l’orun.
- Awon angeli njuba Re
Won nyin O fun titobi Re
Agbara Re ko ni afiwe
Iwo l’O da ohun gbogbo
L’aye ati l’orun. -
Gbogbo awon ti igbaani
Ni won ngbe oruko Re ga
Won nroyin ise agbara Re
Ti O nse ni igba gbogbo
L’aye ati l’orun. -
Ni gbogbo agbaye l’oni
Ni awon omo Olorun
Nkorin iyin si oruko Re
Ti won nsoro titobi Re
L’aye ati l’orun. -
Olorun wa wa kawaye
K’a wa pelu le juba Re
K’a le fi aye wa se ‘fe Re
K’a si le gbadun ore Re
L’aye ati l’orun. -
Olorun wa Olotito
Ko si aseti l’odo Re
Gba wa l’owo gbogbo bilisi
K’a wa le jere igbagbo
L’aye ati l’orun.
Z. A. Ogunsanya, 5/10/2018. I wrote this song for the funeral of
my mother, who died on 2/10/2018 and was buried
on 5/10/2018 at the estimated age of 99.