HYMN – ORI MI KO NI BURU O

ORI MI KO NI BURU O
Composed by Z. A. Ogunsanya, 15/11/2019.
During the night of miracles programme in the church.

1. Ori mi ko ni buru o
Aye mi ko ni baje o
Ibi kankan ko ni je t’emi
Baba l’oke ti sure fun mi o.

Egbe: Ire t’o su fun mi
O ti mo mi l’ori
Baba l’oke ti sure fun mi.

2. Ese ko ni bori mi o
Esu ko ni ri mi mu o
Ipeyinda ko ni je t’emi
Baba l’oke ti ramipada o.

3. Okan mi ko ni daru o
Ebi mi ko ni daru o
Ibanuje ko ni je t’emi
Baba l’oke ti fun mi l’ayo o.

4. Aya (oko) mi ko ni buru o
Omo mi ko ni seku o
Ewu k’ewu ko ni wu wa o
Baba l’oke ti fun wa n’ire o.

5. Ise mi ko ni daru o
Osi kan ko ni ta mi o
Adanu kan ko ni je t’emi
Baba l’oke ti bukun fun mi o.

6. Epe kan ko ni mo mi o
Iya kan ko ni je mi o
Idamu kan ko ni je t’emi
Baba l’oke ti segun fun mi o.

7. Oni mi ko ni buru o
Ola mi ko ni baje o
Orun egbe ko ni je t’emi
Baba l’oke yo mu mi de’le o.