ONIGBAGBO E F’OKANBALE
Composed by Z. A. Ogunsanya, 10/6/2019. While meditating in my room on my bed in the night.
1. Onigbagbo e f’okanbale (k’e lo tujuka)
Isoro wa fun ‘gba die ni (ko tun nipe mo)
A o goke lo ni aipe (laipe rara)
S’odo Jesu n’ile Baba Re (n’ile ologo o).
Egbe: Ko ni pe mo ti ipe yo dun
T’a o fo lo pade Oluwa
Omo Olorun e f’okanbale
Ojo ayo wa ti sunmole.
2. Gba ti a ba de oke orun (ni ilu ogo)
Ni odo Jesu Oluwa wa (n’ile alayo)
A o ri gbogbo awon ara (awon ore wa)
Ti won ti koja lo saju wa (l’at’igba pipe o).
3. A o ri Jesu Oluwa wa (ninu ogo Re)
A o f’owo kan apa iso (t’a fi kan mo’gi)
A o ri apa ade egun (t’a fi de l’ori)
At’iho oko ni egbe Re (A o si dupe o).
4. A o ri awon aposteli (Gbogbo won pata)
Peteru, Jonu, ati Paulu (ati bee bee lo)
A o ri awon arabinrin (l’omode l’agba)
Ati gbogbo awon iyoku (Gbogb’onigbagbo o).
5. A o fo mo gbogbo l’orun (pelu ayo nla)
A o jumo ko orin ayo (fi gbe Baba ga)
A o jo je ase Oluwa (ti Yo se fun wa)
Ninu ayo ti ko nipekun (ti ayeraye o).
6. A o gba ade onirawo (ade ologo)
A o gba ere fun ise wa (t’a se ni aye)
A o gba ibugbe t’o dara (n’ile ologo)
Ayo wa ki yo ni ipekun (n’ile wa l’oke o).
7. Ni ile wa ni oke orun (ti Jesu npese)
Isoro kan ko le de ibe (ni onakona)
Ibanuje ki yo le de be (ni onakona)
Kiki ayo ni a o ma yo (l’odo Oluwa o).