OLORUN MI, MO WA YIN O O
<em>Egbe: Olorun mi, mo wa yin O o
Olorun mi, mo wa gbe O go
Olorun mi, mo wa yin O o
Ore t’E se fun mi, o po, o tobi.
- Ore t’igbala mi, ore t’iwenumo.
Ore t’agbara Re, o po, o tobi. -
Ore fun obi mi, ore fun aya mi
Ati t’awon’mo mi, o po, o tobi. -
Ore t’oju ala, ore t’irin ajo
Ore n’igba gbogbo, o po, o tobi. -
Ore ninu’le mi, ore n’ib’ise mi
Ore n’ibi gbogbo, o po, o tobi. -
Ore t’iwosan Re, ore t’ilera Re
T’ara, t’okan, t’emi, o po, o tobi. -
Ore t’imisi Re, ore t’isegun Re
Ore l’ona gbogbo, o po, o tobi. -
Ore ti abo Re, ore t’ipese Re
Ore t’iranwo Re, o po, o tobi. -
Ore t’idalare, ore t’oju rere
T’ibale okan mi, o po, o tobi. -
Ore t’ojo oni, t’ojo rere l’ola
Ati t’ayeraye, o po, o tobi.
Z. A. Ogunsanya, 17/2/2018. In the church on Saturday, while
thanking God for another workers’ meeting.