- Oju mi ti mo ni Baba Iwo l’O fun mi
Eti ti mo fi un gboran Iwo l’O fun mi
Enu ti mo fi un s’oro yi o
Baba Iwo l’O fi se mi l’oore
Ati nitori eyi, Baba, mo wa dupe o
Fun ore Re, ti O un se l’aye mi.
Egbe: Kabiyesi, Baba mi Mimo oloore
Ore t’E se fun mi, o po oga yeye
Mo wa dupe o, Baba, E se o.
- Ile ti mo un gbe Baba Iwo lo fun mi
Aya mi t’o nd’aso bo mi Iwo l’O fun mi
Awon omo mi t’o yi mi ka o
Baba Iwo l’O fi won tami l’ore
Ati nitori eyi, Baba, mo wa yin O o
Fun ore Re, ti O un se l’aye mi. -
Igbala okan mi Baba Iwo l’O fun mi
Ni t’iwenumo okan mi Iwo l’O fun mi
Ati agbara Emi Mimo o
Baba Iwo l’O fi ro mi l’agbara
Ati nitori eyi, Baba, mo mu’jo jo o
Fun ore Re, ti O un se l’aye mi. -
Isimi ti mo ni Baba Iwo l’O fun mi
Ireti ile ologo Iwo l’O fun mi
Ati isegun l’ori Esu o
Baba Iwo l’O fi se mi ni akin
Ati nitori eyi, Baba, mo juba Re o
Fun ore Re, ti O un se l’aye mi.
Z. A. Ogunsanya, 25/12/2018. On my bed, between around 11:50 and 12:35.