HYMN – OJO IDAJO TI FERE DE O

OJO IDAJO TI FERE DE O
Composed by Z. A. Ogunsanya, 2/9/2019. In my room, in the evening, after ministering at the interdenominational Bible study for church leaders.

Egbe: Ojo idajo ti fere de o (O ti de tan)
Gbogbo eniyan e mura sile (yanju, yanju)
Eni t’o ba de ba l’ojiji (laimura)
Adanu ayeraye ni o (O ti daju).

1. L’ojo idajo, owo ti o da
N’ile Oluwa, ko ni le gba o
L’ojo idajo, orin ti o ko
Fi gb’Oluwa ga, ko ni le gba o
Ohun ti yo le gba o ni
Ironupiwada, kuro ninu gbogbo ese re
Ati igbagbo re, ninu Jesu Ologbala.

2. L’ojo idajo, esin ti o se
N’ile Oluwa, ko ni le gba o
L’ojo idajo, ise ti o se
N’ile Oluwa, ko ni le gba o
Ohun ti yo le gba o ni
Ibalo t’o dara, pelu Olorun ni otito
Ati sise ife, Olorun ni igba gbogbo.

3. L’ojo idajo, opo yo sokun
Sugbon ekun won, ko ni le gba won
L’ojo idajo, opo yo ro’jo
Sugbon ejo won, ko ni le gba won
Ohun ti yo le gba won ni
Kiko Esu sile, ki won to fi aye yi sile
Ati sisa f’ese, ki won f’ara mo Olorun.