NI BIBLE PATTERN CHURCH, OSO KII SO WA RARA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 6/8/2019. In my room, as I returned from the Radio station at Matogun, where I went to be interviewed about BPC confab starting the following day.
1. Ni Bible Pattern Church (Oso kii so wa rara)
Ni Bible Pattern Church (Aje kan kii je wa o)
Ni Bible Pattern Church (Epe kan ko le mo wa rara)
Baba ti bukun fun wa o (Ogungun kan kan ko le ran wa)
Baba ti bukun fun wa o (Ipa aye kan ko le ran wa)
Baba ti bukun fun wa o ooo (Aye ti pofo tan l’ori wa).
Egbe: Gbogbo aye e wa o (si Bible Pattern Church)
Gbogbo eniyan e wa (si Bible Pattern Church)
T’e ba fe d’omo Olorun (E wa)
T’e be fe s’ori rere (E wa)
T’e ba fe d’eni ibukun (E wa)
T’e ba fe abo t’odaju (E wa)
T’e ba fe wo’le ologo (E wa)
E wa, e wa o (si Bible Pattern Church)
Gbogbo yin e wa o (si Bible Pattern Church)
L’omode l’agba e wa (si Bible Pattern Church)
Aye yin yo toro (ni Bible Pattern Church).
2. Ni Bible Pattern Church (Iran eke ko si rara)
Ni Bible Pattern Church (Etan kan kan ko ma si o)
Ni Bible Pattern Church (A kii f’ipa gb’owo rara)
Alabukun fun ni wa o (Ofe ni gbogbo adura wa)
Alabukun fun ni wa o (A kii s’epe fun eniyan)
Alabukun fun ni wa o ooo (Esu ti pofo tan l’ori wa).
3. Ni Bible Pattern Church (Oro orun je wa logun)
Ni Bible Pattern Church (Ife otito l’ani o)
Ni Bible Pattern Church (Oro ija kan ko si rara)
Alabukun fun ni wa o (Bi ebi l’a se un ba’ra lo)
Alabukun fun ni wa o (Ko si rikisi ati ote)
Alabukun fun ni wa o (Ayo l’a fi un s’ohun gbogbo).