MO SUN MI JI, L’OJO ONI O
- Mo sun mo ji, l’ojo Oni o
Mo gbe owo, mo gbe ese
Mo si tun le k’orin
Mo si tun ka Iwe Mimo
Enu mi la, mo le gba adura
Ogo ma ni fun O o Baba.
Egbe: Ogo ma ni fun O o Baba (Baaba)
Ogo ma ni fun O o Baba
Aanu Re l’o po l’aye mi (l’aye mi o)
Ogo ma ni fun O o Baba.
- Mo je mo mu, inu ko run mi
Mo lo s’oke, mo lo s’odo
Mo r’e ‘le ijosin
Mo si lo s’ibi ise mi
Ibi kan kan ko ya si ile mi
Ogo ma ni fun O o Baba. -
Gbogbo ipa, ti Esu ti sa
Igbiyanju, awon ti re
Ofo ni won ja si
Idanwo ko si bori mi
Alagbara ti f’okan mi bale
Ogo ma ni fun O o Baba.
Z. A. Ogunsanya, 12/2/2018. On my bed, early in the morning.