HYMN – MO NILO RE OLORUN MI

MO NILO RE OLORUN MI

  1. Mo nilo Re Olorun mi
    Mo nilo Re l’ojo gbogbo
    Fi agbara Re di mi mu o
    Ma je k’e mi subu o
    Oga ogo ramilowo
    Iwo nikan ni mo mo
    Iwo nikan ni mo ni
    Oga ogo ramilowo.
  2. Mo nilo Re Olugbala
    Mo nilo Re n’ibi gbogbo
    Fi anu Re ti mi l’eyin o
    Ma je k’are mu mi o
    Alagbara ranmilowo
    Iwo nikan ni mo mo
    Iwo nikan ni mo ni
    Alagbara ranmilowo.

  3. Mo nilo Re Emi Mimo
    Mo nilo Re l’ona gbogbo
    Fi otito Re gbemiro o
    Ma je k’e mi sise o
    Olutunu ranmilowo
    Iwo nikan ni mo mo
    Iwo nikan ni mo ni
    Olutunu ranmilowo.

Z. A. Ogunsanya, 5/12/2018 In the church, while
leading prayer under fasting and prayer programme.