HYMN – MO GBE O GA, JESU MI MO GBE O GA

MO GBE O GA, JESU MI MO GBE O GA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 16/09/2016

1. Mo gbe O ga, Jesu mi mo gbe O ga
Eni keji Olorun Metalokan
Iwo l’o da gbogbo aye at’orun
Mo gbe O ga, Jesu mi mo gbe O ga.

Egbe: Eni ba mo Jesu yi, k’o ba mi gbe ga
(Mo gbe ga, Mo gbe ga)
Eni ba mo Jesu yi, k’o ba mi yin l’ogo
(Mo f’ogo, fun Jesus)
Ko s’eni t’o mo Jesu, ti ki yoo fi ogo fun
Eni ba mo Jesu yi, k’o ba mi gbe ga.

2. Mo feran Re, Jesu mi mo feran Re
Ife Re mu k’O ku fun mi l’ori’gi
Emi pelu feran Re t’okan t’okan
Mo feran Re, Jesu mi mo feran Re.

3. Mo jeri Re, Jesu mi mo jeri Re
Agbara Re nikan ni ko l’afiwe
O daju pe Iwo ni yoo se t’emi
Mo jeri Re Jesu mi mo jeri Re.

4. Mo gba O gbo, Jesu mi mo gba O gbo
Gbogb’oro Re je otito ati’ye
Oro Re ni o fi nto isise mi
Mo gba O gbo, Jesu mi mo gba O gbo.

5. Ti’Re l’emi, Jesu mi ti’Re l’emi
Ipo yo wu ti mo le wa ni aye
L’osan l’oru l’emi yo ma se ‘fe Re
Ti’Re l’emi, Jesu mi ti’Re l’emi.
6. Ran mi lowo, Jesu mi ran mi lowo
Ma je k’Esu ati ese segun mi
Ki idekun aye mase bori mi
Ran mi lowo, Jesu mi ran mi lowo.

7. Mu mi de’le, Jesu mi mu mi d’ele
Ireti mi ko si ninu aye yi
Ijoba Re nikan ni’reti mi wa
Mu mi de’le, Jesu mi mu mi d’ele.