HYMN – MENU RE JE, SATANI MENU RE JE

MENU RE JE, SATANI MENU RE JE

Composed by Z. A. Ogunsanya, 19/10/2019. In my room, on a Saturday evening, my mouth suddenly began to sing this song without any precondition, as I was trying to appreciate how God made me to write two songs in quick succession, within a short time: the two songs are, “Da’wo le mi Baba Mimo da’wo le mi o” and “Oye k’amaa dupe, o ye k’a maa yin Baba o”.

1. Menu re je, Satani menu re je (opuro)
Menu re je, Satani menu re je (eleke)
Sebi ‘wo l’o sope, “Ko si Olorun kan n’ibi kankan”
Sungbon un ko, iwala-aye mi, ta l’o fi fun mi (Maa dahun)
Aye ti a un gbe, ta l’Eni t’O da (Maa fesi)
Ohun gbogbo ti mo ni l’aye yi o, se’wo l’o fi fun mi (sio)
Menu re je, Satani menu re je (O un paro)
Menu re je, Satani menu re je.

Egbe: Iro ti o pa titi, ti a fi le o sokale l’orun
Iro t’o pa f’awon angeli, ti won fi di emi oknkun
Eyi ti o pa, fun Baba Adamu, at’iyawo re
L’o fi ba gbogbo aye won je (t’omo, t’omo)
Ohun l’o tun fe maa pa fun mi (agba opuro)
Menu re je, Satani menu re je.

2. Menu re je, Satani menu re je (opuro)
Menu re je, Satani menu re je (eleke)
Iwo l’o tun sope “ko si Jesu kankan n’ibi kankan”
Sungbon un ko, bibo l’owo ese, ta l’o fi fun mi (Maa dahun)
Igbala okan mi, ta l’o fi fun mi (Maa fesi)
Ayo igbala ti mo wa ni yi o, se’wo l’o fi fun mi (sio)
Menu re je, Satani menu re je (O un paro)
Menu re je, Satani menu re je.

3. Menu re je, Satani menu re je (opuro)
Menu re je, Satani menu re je (eleke)
Be e l’o tun sope, “ko s’ilodi ninu ese kankan”
Sugbon un ko, elese t’atijo, ki l’o ko ba won (Maa dahun)
Oloro t’o wona, ki l’o sun de be (Maa fesi)
Lilo s’orun apadi Judasi o, ise ese ha ko (sio)
Menu re je, Satani menu re je (O un paro)
Menu re je, Satani menu re je.

4. Menu re je, Satani menu re je (opuro)
Menu re je, Satani menu re je (eleke)
O ko saisope, “ko si orun kankan n’ibi kankan”
Sugbon un ko, alafia okan, n’ibo l’o ti nwa (Maa dahun)
Itoni Olorun, n’ibo l’o ti nwa (Maa fesi)
Ireti orun ti mo wa ni yi o, s’odo re l’o ti wa (sio)
Menu re je, Satani menu re je (O un paro)
Menu re je, Satani menu re je.