MA SOKUN ONIGBAGBO
Composed by Z. A. Ogunsanya, 14/2/2019. In my room, this song started with just humming in my heart during fasting and prayer.
1. Ma sokun onigbagbo
Ohun yowu k’o le de
Olorun mo gbogbo won
Jesu yo bojuto won fun o.
Egbe: Ko si ileri ninu oro Olorun
Pe onigbagbo ko ni ni isoro
Sugbon ileri Olorun ni wipe
Isoro ko ni bori onigbagbo
Onigbagbo otito ninu Jesu ni
Ore mi, taku ti Jesu o
Ma sokun mo rara, ati rara
Gbekele Olorun.
2. B’ Esu ba gb’ogun ti o
B’o se aisan l’o dide
B’o se isoro owo
Jesu yo bojuto won fun o.
3. Bi ore ja o kule
Bi obi ko o sile
Bi aye ba nkegan re
Jesu yo bojuto won fun o.
4. B’o se ‘soro ti emi
B’o se ‘soro idile
B’o si se ni’bi ise
Jesu yo bojuto won fun o.
5. Bi eru ba un ba o
Bi okan re ba daru
B’o si se ibanuje
Jesu yo bojuto won fun o.