MA SOKUN ONIGBAGBO
Composed by Z. A. Ogunsanya, 14/2/2019. In my room, this song started with just humming in my heart during fasting and prayer.
- Ma sokun onigbagbo
Ohun yowu k’o le de
Olorun mo gbogbo won
Jesu yo bojuto won fun o.
Egbe: Ko si ileri ninu oro Olorun
Pe onigbagbo ko ni ni isoro
Sugbon ileri Olorun ni wipe
Isoro ko ni bori onigbagbo
Onigbagbo otito ninu Jesu ni
Ore mi, taku ti Jesu o
Ma sokun mo rara, ati rara
Gbekele Olorun.
-
B’ Esu ba gb’ogun ti o
B’o se aisan l’o dide
B’o se isoro owo
Jesu yo bojuto won fun o. -
Bi ore ja o kule
Bi obi ko o sile
Bi aye ba nkegan re
Jesu yo bojuto won fun o. -
B’o se ‘soro ti emi
B’o se ‘soro idile
B’o si se ni’bi ise
Jesu yo bojuto won fun o. -
Bi eru ba un ba o
Bi okan re ba daru
B’o si se ibanuje
Jesu yo bojuto won fun o.