KERE O, GBOGBO EYIN OMO OLORUN
Z. A.Ogunsanya, 6/3/2016
Ibere: Kere o (kere /3ice)
Gbogbo eyin omo Olorun
E lo si gbogbo agbaye
E so fun gbogbo eniyan wipe
Jesu nikan ni Olugbala /2ice
Ki l’e ti wi (Jesu nikan ni Olugbala).
- Ti e ba ti de odo awon arugbo
E so fun won wipe
Igba ko lo bi orere mo
Ojo aye omo eniyan un ku ferefere
Eni t’o ba ku lairi igbala Jesu
Orun apadi ni yo ti lo ayeraye
Jesu nikan ni Olugbala.
Egbe: Ki l’e ti wi (Jesu nikan ni Olugbala)
E tun wi ki ngbo (Jesu nikan ni Olugbala)
Ohun ni wundia bi (Jesu nikan ni Olugbala)
T’O ku fun gbogbo araye (Jesu nikan ni Olugbala)
T’O ji dide l’ojo keta (Jesu nikan ni Olugbala)
Ti O goke lo si orun (Jesu nikan ni Olugbala)
Ti O si tun npada bo wa (Jesu nikan ni Olugbala)
Ti yo se idajo aye (Jesu nikan ni Olugbala)
E tun tun so leekan si (Jesu nikan ni Olugbala)
Ko tun si olugbala miran mo rara
Jesu, nikan l’Olugbagba.
- Ti e ba si ti de odo awon odo
E so fun won wipe
Adun aye fun’gba die ni
Anilati ko gbogbo ese sile pata pata
Enit’o ba ko l’ati wa igbala Jesu o
L’at’aye ni yo ti jiya lo s’ayeraye
Jesu nikan ni Olugbala. -
Ti e ba ti de odo awon omode
E so fun won wipe
T’ewe t’agba l’o nilo Jesu
Ire ayo ati alafia ni gbigba Jesu
Enikeni ti ko ba fi aye re fun Jesu
Radarada ni Esu yo se aye re o
Jesu nikan ni Olugbala. -
Ti e ba ti de odo awon olowo
E so fun won wipe
Owo aye ko wulo l’orun
Ase olodumare ni pe ki a gba Jesu gbo
Olowo pelu un lo si orun apadi
Dan dan ni gbigba Jesu fun gbogbo eniyan
Jesu nikan ni Olugbala. -
Ti e ba ti de odo awon talaka
E so fun won wipe
Awon pelu nilo Jesu yi
Osi ko le si’lekun orun fun eni kan kan
A ko nilo owo lati igbala Jesu
Ofe ni igbala Jesu fun gbogbo eniyan
Jesu nikan ni Olugbala. -
Ti e ba ti de odo awon elesin
E so fun won wipe
Esin ko le gbeni de orun
Jesu Oluwa ni ona otito ati iye
Enit’o ba fi esin dipo igbala Jesu
Jale ayeraye ni yo fi maa kabamo
Jesu nikan ni Olugbala. -
T’e ba ti de odo awon onigbagbo
E so fun won wipe
Dan dan ni lati waasu Jesu
Ki won mase maa huwa ika si awon elesin
Nipa sisope okan l’esin ati Jesu
O lodi l’ati ma fi Jesu han elesin
Jesu nikan ni Olugbala.
Ipari: Kere o (kere /3ice)
Gbogbo eyin omo Olorun
E lo si gbogbo agbaye
E so fun gbogbo eniyan wipe
Jesu nikan ni Olugbala
Ki l’e ti wi (Jesu nikan ni Olugbala).