KABIYESI BABA OLOGOJULO
Composed by Z. A. Ogunsanya, 5/8/2019. From my sleep, as I was observing siesta after ministering at the interdenominational Bible study for church leaders.
1. Kabiyesi Baba Ologojulo
Iwo l’O ga julo ninu ohun gbogbo
Agbara Re Baba ko ni afiwe
Kabiyesi Re o Baba ninu aye mi
Kabiyesi (Ologojulo) Kabiyesi o (Baba)
Kabiyesi Re o Baba Ologojulo.
2. Kabiyesi Baba Awimayehun
Iwo l’O l’agbara lori ohun gbogbo
Agbara Re Baba kiibati ni
Kabiyesi Re o Baba ni ojo oni
Kabiyesi (Awimayehun) Kabiyesi o (Baba)
Kabiyesi Re o Baba Awimayehun.
3. Kabiyesi Baba Atofarati
Iwo l’O le gbani lowo ewu gbogbo
Agbara Re Baba l’o le ja ide
Kabiyesi Re o Baba ni ojo gbogbo
Kabiyesi (Atofarati) Kabiyesi o (Baba)
Kabiyesi Re o Baba Atofarati.
4. Kabiyesi Baba Alewilese
Iwo l’O le mu ni de ile ologo
Agbara Re Baba l’o le gbeniro
Kabiyesi Re o Baba ni ayeraye
Kabiyesi (Alewilese) Kabiyesi o (Baba)
Kabiyesi Re o Baba Alewilese.