HYMN – JESU IWO L’OBA L’ONI YI

JESU IWO L’OBA L’ONI YI
Composed by Z. A. Ogunsanya, 6/12/2017. As I got up from the bed in the morning.

  1. Jesu Iwo l’Oba l’oni yi
    Oba l’oni, Oba l’ola, Oba titi aye
    Oba ni O o, Baba ni ojo gbogbo.

Egbe: Oba, Oba nla ni O
Jesu Oluwa, Iwo nikan l’Oba
Ni gbogbo agbaye.

  1. Jesu Iwo l’Oba l’ebi mi
    Oba t’emi, ti aya mi, ti awon omo mi
    Oba ni O o, Baba ninu Ile mi.

  2. Jesu Iwo l’Oba l’okan mi
    Oba l’oro, Oba l’ero, n’iwa at’ise mi
    Oba ni O o, Baba ninu aye mi.

  3. Jesu Iwo l’Oba l’aye yi
    Oba l’aye, Oba l’orun, Oba n’ibi gbogbo
    Oba ni O o, Baba l’aye at’orun.