IYANU NI O OLUWA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 25/8/2019. In my bathroom early in the morning, as I was to get ready to go for Sunday fellowship.
Egbe: Iyanu ni O Oluwa
Iyanu ni O o Baba
Iyanu ni O o Olorun mi
Iyanu n’ise Re ninu aye mi.
1. Iwo t’O da aye at’orun
Iwo t’O la’na l’arin okun
Iwo ti O gba okan mi la
Iyanu ni O o Olorun mi.
2. Iwo ti O segun Farao
Iwo t’O segun Goliati
Iwo t’O segun Esu fun mi
Iyanu ni O o Eleruniyin.
3. Iwo t’O ran mana l’atorun
T’O so mara di omi didun
Iwo ti O ko arun mi lo
Iyanu ni O o Eledumare.
4. Iwo t’O gbe amukun dide
Iwo ti O la’ju afoju
Iwo ti O m’aditi gboran
Iyanu ni O o Atof’arati.
5. Iwo ti O mu odi f’ohun
Iwo ti O we adete mo
Iwo ti O so mi di mimo
Iyanu ni O o Ologojulo.
6. Iwo t’O ndahun adura mi
Iwo t’O fun mi l’alafia
Iwo t’O fi ayo Re kun mi
Iyanu ni O o Alewilese.
7. Iwo t’O wo odi Jeriko
Iwo ti O segun Sisera
Iwo ti O mu mi l’arada
Iyanu ni O o Awimayehun.
8. Iwo ti O ku t’O tun jinde
Iwo t’O goke lo si orun
Iwo ti yo pada wa mu mi
Iyanu ni O o Ajinde iye.