HYMN – IWO NI MO GB’OJU MI LE

IWO NI MO GB’OJU MI LE
Composed by Z. A. Ogunsanya, 28/6/2019. During missionary journey to Bible Pattern Church Abuja, inside Bro. Tunde’s room, and on the way to the airport

Egbe: Iwo ni mo gbe oju mi le
Iwo ni mo fi eyin mi ti
Atof’arati, Olorun mi
Mase je ki oju ti mi.

1. Esu un hale mo mi, ni ojojumo
O sope ko s’ireti fun mi l’odo Re Baba
Sugbon mo gba O gbo
Ireti wa fun mi, l’odo Re Baba.

2. Esu tun pa’ro fun mi, O tun so wipe
Asedanu ni mo un se ni odo Re Baba
Sugbon mo gba O gbo
Ere un be fun mi, l’odo Re Baba.

3. Esu ko siwo lati, ma yo mi l’enu
Bi O ti yo Jesu Kristi Oluwa mi l’enu
Sugbon mo gba O gbo
Isegun wa fun mi, l’odo Re Baba.

4. Esu un sa ipa re, k’emi le segbe
O un se akitiyan ki emi le ma dese
Sugbon mo gba O gbo
Iyege wa fun mi, l’odo Re Baba.