HYMN – IWO L’ANA, IWO L’ONI

IWO L’ANA, IWO L’ONI

Composed by Z. A. Ogunsanya, 24/10/2019. In my room after Thursday hour of miracles.

Egbe: Iwo l’ana, Iwo l’oni
Iwo l’ola at’ojo gbogbo
Baba l’oke ti mo gbekele o
Iwo ni ohun gbogbo fun mi.

1. Aseyori ti ana, Iwo l’O fi fun mi
Aseyori ti oni o, Iwo l’O fi fun mi
Eyi ti o un bo l’ona, Iwo l’O fi ranse
Iwo nikan ni mo ni o, l’ati f’eyin mi ti.

2. Ohun ti mo je l’ana, Iwo l’O fi fun mi
Ohun ti mo je l’oni o, Iwo l’O fi fun mi
Eyi ti un o je l’ola, l’O ti un se lowo
Iwo nikan ni mo ni o, fun jije mi mu mi.

3. Ibi ti mo lo l’ana, Iwo l’O so mi lo
Ibi ti mo lo l’oni o, Iwo l’o so mi lo
Eyi ti un o lo l’ola, O tun ma so mi lo
Iwo nikan ni mo ni o, fun lilo bibo mi.

4. Orin ti mo ko l’ana, Iwo l’O fun mi ko
Orin ti mo ko l’oni o, Iwo l’O fun mi ko
Eyi ti un o ko l’ola, iyin Re lo ma je
Iwo nikan ni mo ni o, l’ati ma yin logo.

5. Wiwa l’aye mi l’ana, Iwo l’O damisi
Wiwa l’aye mi l’oni o, Iwo l’O gbemiro
Eyi ti ayeraye mi, odo Re lo ma je
Iwo nikan ni mo ni o, fun ayo ikeyin.