HYMN – IRIN AJO YI, TI MO TI BERE

IRIN AJO YI, TI MO TI BERE
Composed by Z. A. Ogunsanya, 13/9/2016.

  1. Irin ajo yi, ti mo ti bere
    Ni ona tooro, un ko ni w’eyin
    On yo wu k’o de, mo ti pinu re tan
    Ile ologo, ni mo un lo.

Egbe: Mo ti se’leri (se’leri)
Mu ti mura tan (mura tan)
Jesu Oluwa (Oluwa)
Ni uno ma tele (tele)
B’araye fe (b’o fe o)
B’araye ko (b’o ko o)
Un o te le d’ele ologo
Ile ologo o.

  1. Eyin elese, e ma fa mi mo
    Mo be yin k’e wa, gba Jesu yi gbo
    E k’ese sile, k’e d’omo Olorun
    K’ile ologo, le je ti yin.
  2. Esu ko ni’re, kan fun eniyan
    Orun apadi, ni ere t’o ni
    Eni ba te le, nipa dida ese
    Ile ologo, ni yo kuna.

  3. Ipinnu mi ni, l’ati sin Jesu
    Ni’po ki’po ti, mo ba wa l’aye
    Adun aye ki, yo le da mi pada
    Ile ologo, ni mo un lo.

    1. Omo Olorun, e ma rewesi
      Ojo ti lo tan, oru fere de
      E je ka si’se, ni’gba tii se osan
      Ni’le ologo, k’a le gb’ere.
  4. Asan ni aye, ati ogo re
    O le dun l’oni, ekun ni l’ola
    Eni fe aye, ko ni’fe Olorun
    Ni’le ologo, ko s’aye fun.

  5. Eniyan pupo, nw’orun apadi
    Ona abayo, kan soso t’o wa
    K’a k’ese sile, k’a gba Jesu Kristi
    K’ile ologo, le di ti wa.