ILE TUN TI MO L’OJO ONI O
Composed by Z. A. Ogunsanya, 21/11/2019. On my bed around
4:45 am, as I was to start getting ready for Thursday hour of miracles.
1. Ile tun ti mo l’ojo oni o
Baba mi l’oke mo wa dupe o
Opelope Re l’oru ana o
L’aba Esu ko se le mi l’ori.
Egbe: Mo nilo Re o Baba Mimo (Baba Mimo)
Mo nilo Re o l’ojojumo (L’ojojumo)
A fi ti O ba ranmilowo (Baba mi)
L’Esu ko ni le yo le mi l’ori.
2. Bi mo ti un jade lo l’oni o
Baba mi l’oke wa jowo ye o
Ma se je ki ibi k’o ba mi o
K’aba Esu ma se le mi l’ori.
3. Ni ona iye ti mo wa yi o
Baba mi l’oke wa di mi mu o
Ma se je ki ese mi k’o ye o
K’ete Esu ma se le mi l’ori.