HYMN – HALLELUYA FUN ATOOBIJULO


HALLELUYA FUN ATOOBIJULO

Composed by Z. A. Ogunsanya, 22/6/2019.

Egbe: Halleluya (3ice.) fun Atobijulo
Halleluya, Halleluya
Halleluya, l’o ye O o Baba.

1. Iwo nikan l’o to si, ni a se fun O (halleluya)
Iwo nikan l’o ye fun, Baba wa l’oke (halleluya)
Ko tun si elomiran, ti halleluya to si
Iwo nikan l’o to si, gba halleluya wa
Baba, gba halleluya wa.

2. Iwo ni Olugbala, ti O ku fun wa (halleluya)
Iwo l’O tun ji dide, ni ojo keta (halleluya)
Iwo l’o tun goke lo, lati soju wa l’orun
Iwo ni ope to si, gba halleluya wa
Baba, gba halleluya wa.

3. Iwo l’O fi eje Re, we okan wa mo (halleluya)
Iwo l’O tun fi Emi, Mimo Re kun wa (halleluya)
O si tun fi ayo ati alafia fun wa
Iwo ni iyin to si, gba halleluya wa
Baba, gba halleluya wa.

4. Iwo l’O un gbadura, fun wa ni orun (halleluya)
Iwo ni yo wa mu wa, lo sile ogo (halleluya)
Iwo ni yo de wa ni, ade ologo l’orun
Iwo ni ogo to si, gba halleluya wa
Baba, gba halleluya wa.