GBOGBO ORO TI E UN SO FUN WA L’O JE OTITO O
Composed by Z. A. Ogunsanya, 23/11/2019. In my room, in the morning, after the madden edition of teenagers’ vigil in the church.
1. Gbogbo oro ti E un so fun wa
Olorun wa, l’o je otito o
Gbogbo ise ti E un se fun wa
Olorun wa, l’o wulo fun wa
Boya o ye wa tabi ko ye wa
Olorun wa, Eyin l’Abanidaro o.
Egbe: Baba ye, tubo ranwalowo
Olu orun ye o, jare gbo adura wa
K’oju ma ti wa lae lae.
2. Ona Re ti E la sile fun wa
Olorun wa, l’ona otito o
Gbogbo ase ti E un pa fun wa
Olorun wa, l’o je fun ire wa
Boya o ye wa tabi ko ye wa
Olorun wa, Eyin l’Olutoju wa o.
3. Iyanu Re ti E un se fun wa
Olorun wa, ko ma l’afiwe o
Iranwo Re ti E un se fun wa
Olorun wa, n’ifokanbale wa
Boya o ye wa tabi ko ye wa
Olorun wa, Eyin l’Agborodun wa o.
4. Ile Re l’oke t’E fe mu wa lo
Olorun wa, n’ile ologo o
Ona toro ti E un mu wa rin
Olorun wa, l’o yori s’ayo wa
Boya o ye wa tabi ko ye wa
Olorun wa, Eyin l’Afinimona o.