HYMN – GBOGBO OMO OLORUN E WA

GBOGBO OMO OLORUN E WA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 26/10/2019. In my room, on Saturday evening, after writing the song titled “Ire l’ana, ire l’oni”.

Egbe: Gbogbo omo Olorun e wa (E sare wa)
Gbogbo onigbagbo e wa o (E sumo bi)
E wa k’a jo yin Jesu logo (K’a si gbega)
Ore Re po pupo l’aye wa (O ti daju).

1. Awa t’o ti rin lo jina ni inu ese
Awa t’o ti sina jina l’ona iparun
Awa t’Esu ti so d’omo egbe yanju yanju
Awa l’o tun wa ri, ti O dariji wa, ti O si gba wa la
Ti O si tun we okan wa mo, t’O si fun wa, l’Emi Re.

2. Awa t’Esu at’ese ti fi s’inu ide
Awa t’ota at’aye ti ngbogunti gidi
Awa ti ko ni ifokanbale kan kan rara
Awa l’O segun fun, ti O ja ide wa, ti O tu wa sile
Ti O si fun wa l’ominira, nipa t’emi, at’ara.

3. Awa ti ibanije da ori re kodo
Awa t’eru at’ipaya ko fun n’isimi
Awa ti ko n’ireti kan kan ninu aye
Awa l’O sure fun, t’O fun l’alafia, ti O fun ni ayo
Ti O si wa fun ni ireti, ile ogo, n’ikeyin.