HYMN – GBOGBO OKE ATI PETELE

GBOGBO OKE ATI PETELE
Composed by Z. A. Ogunsanya, 16/8/2019. While meditating in my room in the morning.

Egbe: Gbogbo oke ati petele
Baba mi l’o da gbogbo won
At’Okun at’Iyangbe ile
Baba mi l’o se gbogbo won
Ko s’ohun ti Baba ko le se
F’enikeni t’o ba gbekele.

1. Gbogbo eyin ti ori un fo
E gbe ori yin to Jesus wa
Gbogbo eyin ti inu un run
E gbe inu yin to Jesus wa
Jesu yi o ni Oluwa l’ori gbogbo isoro.

2. Gbogbo eyin ti o fo l’oju
E gbe oju yin to Jesus wa
Gbogbo eyin ti aye un se
E gbe aye yin to Jesus wa
Jesu yi o ni Oluwa l’ori gbogbo isoro.

3. Gbogbo eyin ti o ro l’apa
E gbe apa yin to Jesus wa
Gbogbo eyin ti o ro l’ese
E gbe ese yin to Jesus wa
Jesu yi o ni Oluwa l’ori gbogbo isoro.

4. Gbogbo eyin ti o ya odi
E gbe enu yin to Jesus wa
Gbogbo eyin ti o y’aditi
E gbe eti yin to Jesus wa
Jesu yi o ni Oluwa l’ori gbogbo isoro.