HYMN – ESU TI KUNA O BABA, E JE K’O TUBO MA KUNA LO

ESU TI KUNA O BABA, E JE K’O TUBO MA KUNA LO
Composed by Z. A. Ogunsanya, 11/12/2019. In my room in the morning, as I finished writing line 2 of stanza 5 of a song titled “Mo nilo iranlowo Re Oluwa”, Sister. Oyebanji senior called and asked me to pray about a neighbor’s 15 year old child, that went to work but did not return. I gave God an ultimatum with a vow of 1,000 hallelujah. After the prayer, I slept. By the time I woke-up few hours latter, the child was already found: hallelujah. As I was on my kneels shouting the hallelujah to fulfill my vow, this song began to ring in my heart.

Ibere: Esu ti kuna o Baba )
E je k’o tubo maa kuna lo) /2ice.
Gbogbo ipa re ni aye wa (pata pata)
Ofo, ofo ni k’o yori si.

1. B’o ba fe ji wa l’omo gbe (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o ba fe fi arun se wa (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o s’ebi l’o fe fi pa wa (Ofo, ofo ni k’o yori si)
Esu ti kuna o Baba (E je k’o tubo ma kuna lo).

2. B’o fe da wa pada s’aye (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o fe ti wa s’inu ese (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o se’gbala l’o fe ji lo (Ofo, ofo ni k’o yori si)
Esu ti kuna o Baba (E je k’o tubo ma kuna lo).

3. B’o ba fe da wa l’ori ru (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o ba fe da wa l’okan ru (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o se’le wa l’o fe daru (Ofo, ofo ni k’o yori si)
Esu ti kuna o Baba (E je k’o tubo ma kuna lo).

4. B’o fe ki osi k’o ta wa (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o fe ki iya k’o je wa (Ofo, ofo ni k’o yori si)
B’o fe ran wa s’orun egbe (Ofo, ofo ni k’o yori si)
Esu ti kuna o Baba (E je k’o tubo ma kuna lo).