ENI T’O GBA JESU KRISTI GBO, OHUN L’O YE K’O MU IJO JO
Composed by Z. A. Ogunsanya, 26/8/2019. Early in the morning, as I came out of the bathroom and I was to dress-up to go to church, for the interdenominational Bible study for church leaders.
Egbe: Eni t’o gba Jesu Kristi gbo
Oun l’o ye k’o mu ijo jo (ijo repete)
Eni t’o gba Jesu Kristi gbo o
Oun l’o ye k’o ma yo sese (ayo repete)
Ore t’o ga julo, ti a le se fun ara wa
Oun ni k’a gba Jesu Kristi l’Oluwa
Ore t’o ga julo, ti o le se fun ara re
Oun ni k’o gba Jesu Kristi l’Oluwa.
1. L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (l’a dari gbogbo ese re ji o)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo o (ni ko s’eru Esu mo rara)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (l’o d’omo Olorun oga ogo)
Ore gba Jesu Kristi ni Oluwa (ki o le di omo Olorun).
2. L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (l’a ko’ruko re s’iwe iye o)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo o (l’o d’eni ti Jesu nbojuto)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (l’Emi Mimo bere si gbe’nu re)
Ore gba Jesu Kristi ni Oluwa (k’Emi Mimo le ma gbe’nu re).
3. L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (l’ayo Olorun yo kun’nu re o)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo o (ni Jesu yo d’Oluwosan re)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (ni yo ni alafia t’o daju)
Ore gba Jesu Kristi ni Oluwa (k’o le l’alafia t’o daju).
4. L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (l’o kuro l’ona orun egbe o)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo o (l’o bo s’ona ‘joba Olorun)
L’ojo t’enikan gba Jesu Kristi gbo (l’o jogun iye ti ko nipekun)
Ore gba Jesu Kristi ni Oluwa (k’o le n’iye ti ko nipekun).