HYMN – E KU ISE O, BABA MI L’OKE

E KU ISE O, BABA MI L’OKE
Composed by Z. A. Ogunsanya, 10/7/2017.

Egbe: E ku ise o, Baba mi l’oke
E ku ise o, Atofarati
E ku ise o, Baba Ologojulo.

 1. Eyin l’E da aye, l’ati inu ofo
  Eyin l’E f’erupe, mo eniyan s’aye
  Ohun ti E ba wi, nikan ni yo se
  Eyi ti E ba se, ni yo wa pe titi
  Kabiyesi Re, Baba Ologojulo.

 2. Ti E ko ba ko’le, ile ko le duro
  Abo Re Oluwa, l’o le pa ilu mo
  Eni t’E ba sise, ni yo s’aseyori
  Eni t’e ti leyin, nikan l’o le segun
  Mo gbekele O, Baba Ologojulo.

 3. Eyin ti E mi si, l’o le di akuko
  Ibukun Re Baba, l’o le s’oyun d’omo
  Eni t’E ba gbero, ni ko ni le subu
  Eni t’E ba di mu, ni ko ni jin s’ofin
  Mo simile O, Baba ologojulo.

 4. Ni gbogbo agbaye, Eyin ni Oluwa
  Ko tun s’oba biiRe, ni ibomiran mo
  Ko si alagbara, t’o le pe yin n’ija
  Esu alagidi, ko le ko yin l’oju
  Mo f’eyin ti O, Baba Ologojulo.