HYMN – E JE K’A DUPE, E JE K’A YIN BABA L’OGO

E JE K’A DUPE, E JE K’A YIN BABA L’OGO
Composed by Z. A. Ogunsanya. 9/4/2019. In my room, while meditating.

Egbe: E je k’a dupe (E je k’a dupe)
E je k’a yin Baba l’ogo (k’a yin Baba logo)
Ore Baba ni ori wa ko l’afiwe o.

 1. Gbogbo awa t’o mo’nu un ro l’o ye k’a dupe
  O ye k’a dupe fun ore Baba ni ori wa
  Ore Baba ni ori wa ko l’afiwe o.

 2. Gbogbo awa t’o ji l’owuro yi ye k’a dupe
  O ye k’a dupe fun abo Baba l’oju orun
  Opo t’a jo sun l’ana ni ko ji l’oni o.

 3. Gbogbo awa t’o pa da wa ‘le l’o ye k’a dupe
  O ye k’a dupe fun abo Baba n’irin ajo
  Opo t’a jo jade lo ko pa da wa ‘le o.

 4. Gbogbo awa t’o ri je ri mu l’o ye k’a dupe
  O ye k’a dupe fun ‘pese Baba ni ori wa
  Opo ni ko ri je ri mu ninu aye o.

 5. Gbogbo awa t’o gba Jesu gbo l’o ye k’a dupe
  O ye k’a dupe fun igbala Re t’O fi fun wa
  Opo t’a jo wa l’aye ni eru Esu o.

 6. Gbogbo awa t’o nre’le ogo l’o ye k’a dupe
  O ye k’a dupe fun ibugbe t’o nduro de wa
  Opo t’a jo wa l’aye ni yo wo‘na lo o.