E HO IHO AYO SI BABA
Egbe: E ho iho ayo si Baba
E gb’ohun s’oke, E k’orin ogo
Eledumare ma l’ope ye fun.
- Oba t’O gbawala, ti O tun we wa mo.
Oba t’O fi agbara, Emi Re fun wa
A-pata iye ma l’ope ye fun. -
Oba t’O da wa si, l’owo ewu gbogbo
Oba t’O gbe wa duro, ninu igbagbo
Atof’arati ma l’ope ye fun. -
Oba t’O s’abo wa, ni oju ala wa
Oba t’O ba wa un lo, si ibi gbogbo
Eleruniyin ma l’ope ye fun. -
Oba t’O npese fun, gbogbo aini wa
Oba t’O tun fun wa ni, ilera pipe
Alatileyin wa l’ope ye fun. -
Oba t’O fun wa ni, ayo ti ko l’egbe
Oba t’O tun fun wa ni, ireti orun
Orisun iye ma l’ope ye fun.
Z. A. Ogunsanya, 26/5/2018. On my bed after morning workers’ meeting.