BABA RANMILOWO O
Composed by Z. A. Ogunsanya, 7/2/2018.
-
Baba ranmilowo o (l’ona gbogbo)
Baba f’eyin ti mi o (titi d’opin)
Baba se’yanu fun mi (ya mi l’enu)
Baba gbemileke o (a-amin)
Baba gbemileke o
Iwo nikan ni mo ni)
Gbemileke o ) /2ice. -
Baba d’abo bo mi o (n’ibi gbogbo)
Baba pese fun mi o (l’opolopo)
Baba segun fun mi o (l’aseyori)
Baba sure fun mi o (a-min)
Baba sure fun mi o
Iwo nikan ni mo ni)
Sure fun mi o ) /2ice. -
Baba duro ti mi o (n’igba gbogbo)
Baba wa mi si mi o (f’Emi kun mi)
Baba wa gbe mi wo o (pel’agbara)
Baba f’ese mi mule (a-amin)
Baba f’ese mi mule
Iwo nikan ni mo ni)
F’ese mi mule ) /2ice. -
Baba f’Emi Re kun mi (at’ogbon Re)
Baba ro mi l’agbara (fun mi l’okun)
Baba f’ase s’enu mi (ase gidi)
Baba m’adura mi se (a-amin)
Baba m’adura mi se
Iwo nikan ni mo ni)
M’adura mi se ) /2ice. -
Baba ba mi s’oro o (n’gba gbogbo)
Baba si mi l’oju o (oju emi)
Baba f’ara Re han mi (Mu mi mo O)
Baba di mi mu d’opin (a-amin)
Baba di mi mu d’opin
Iwo nikan ni mo ni)
Di mi mu d’opin ) /2ice.