HYMN – BABA RANMILOWO O

BABA RANMILOWO O
BPH 180616-1

  1. Baba ranmilowo o
    Baba f’eyin ti mi o
    Baba sure fun mi o
    Baba gbemileke o
    Iwo nikan ni mo ni )
    Gbemileke o. ) 2ce
  2. Baba wa d’abo bo mi
    Baba wa pese fun mi
    Baba wa segun fun mi
    Baba wa mu mi duro
    Iwo nikan ni mo ni )
    Wa mu mi duro. ) 2ce

  3. Baba wa duro ti mi
    Baba wa mi si mi o
    Baba wa gbe mi wo o
    Baba f’ese mi mule
    Iwo nikan ni mo ni )
    F’ese mi mule. ) 2ce

  4. Baba f’Emi Re kun mi
    Baba ro mi l’agbara
    Baba f’ase s’enu mi
    Baba m’adura mi se
    Iwo nikan ni mo ni )
    M’adura mi se. ) 2ce

  5. Baba ba mi s’oro o
    Baba si mi l’oju o
    Baba f’ara Re han mi
    Baba di mi mu dopin
    Iwo nikan ni mo ni )
    Di mi mu dopin. ) 2ce

               Z. A. Ogunsanya, 7/2/2018.