BABA ONISE ARA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 26/2/2017
Egbe: Baba Onise ara (ara)
Baba Onise iyanu (iyanu)
Baba Onise ara (ara)
Tun wa se’yanu fun wa.
1. B’o s’aye l’o gb’ogun de
Tun wa se’yanu fun wa
B’o s’Esu lo un hale
Tun wa se’yanu fun wa
Ma je k’Esu bori wa o Baba
Tun wa se’yanu fun wa.
2. B’o se aisan l’o de
Tun wa se’yanu fun wa
B’o se ‘soro owo ni
Tun wa se’yanu fun wa
Ma je k’aye yo wa o o Baba
Tun wa se’yanu fun wa.
3. B’o s’oro l’ori aya
Tun wa se’yanu fun wa
B’o s’oro l’ori omo
Tun wa se’yanu fun wa
Ma je ki’damu ba wa o Baba
Tun wa se’yanu fun wa.
4. B’o s’ogun l’oju aye
Tun wa s’eyanu fun wa
B’o s’ogun l’oju ala
Tun wa s’eyanu fun wa
Ma je k’ogun bori wa o Baba
Tun wa s’eyanu fun wa.
5. B’o s’ogun ninu ile
Tun wa s’eyanu fun wa
B’o s’ogun ni’bi ise
Tun wa s’eyanu fun wa
Ma je k’aye bori wa o Baba
Tun wa s’eyanu fun wa.
6. B’o se iberu lo de
Tun wa s’eyanu fun wa
B’o si se idanwo ni
Tun wa s’eyanu fun wa
Ma je k’ese bori wa o Baba
Tun wa s’eyanu fun wa
7. B’o s’ojo iku l’o de
Tun wa s’eyanu fun wa
B’o s’oro ayeraye
Tun wa s’eyanu fun wa
Ma je k’awa segbe o o Baba
Tun wa s’eyanu fun wa.