HYMN – BABA NI MO WA GBE GA O

BABA NI MO WA GBE GA O
Composed by Z. A. Ogunsanya, 2/1/2017. Though not my first song in the year, the first completed hymn in 2018.

Egbe: Baba ni mo wa gbe ga o
Baba ni mo wa yin l’ogo
Baba ni mo wa f’ola fun o
Baba ni ope at’iyin ye.

  1. Mo gbe Baba ga fun igbala (igbala mi).
    Mo gbe Baba ga fun iwosan (iwosan mi)
    Mo gbe Baba ga fun’wenumo (t’O fi fun mi o)
    Baba ni ope at’iyin ye.

  2. Mo gbe Baba ga fun abo Re (n’ibi gbogbo)
    Mo gbe Baba ga fun ipese (opolopo)
    Mo gbe Baba ga fun iranwo (t’O nse fun mi o)
    Baba ni ope at’iyin ye.

  3. Mo gbe Baba fun obi mi (ti won bi mi)
    Mo gbe Baba fun ebi mi (gbogbo ebi)
    Mo gbe Baba fun ijo mi (t’O fi mi si o)
    Baba ni ope at’iyin ye.

  4. Mo gbe Baba fun oni yi (ojo oni)
    Mo gbe Baba fun ola mi (ti mo nreti)
    Mo gbeE ga fun ayeraye mi (n’ile ogo o)
    Baba ni ope at’iyin ye.

  5. Mo gbeE ga fun alafia Re (t’O fi fun mi)
    Mo gbeE ga fun oju rere Re (t’o nfi han mi)
    Mo gbeE ga fun atileyin Re (l’ona gbogbo o)
    Baba ni ope at’iyin ye.