HYMN – BABA MO WA DUPE FUN OJO ONI

BABA MO WA DUPE FUN OJO ONI
Composed by Z. A. Ogunsanya, 5/8/2019. As I woke up in the morning, sitting on my bed, my heart suddenly began to sing the chorus of this song, without any preparation.

Egbe: Baba mo wa dupe, fun ojo oni
Mo tun wa dupe, fun ojo ana o
Ka mi ye Baba, k’emi le tun dupe, fun ojo ola
Ka mi ye Baba, k’emi le ma dupe, fun ojo gbogbo.

1. L’ojo ti ori nfo mi, ti mo ke pe O
Logan l’O dide, ti O le efori jade
L’ojo ti inu nrun mi, ti mo ke pe O
Logan l’O dide, ti O mu inu rirun lo
Ojojumo ni ore Re, ninu aye mi
Baba mo wa dupe, fun ore Re igba gbogbo.

2. L’ojo ti ebi npa mi, ti mo ke pe O
Logan l’O dide, ti O fun mi ni ounje
L’ojo ti ise nse mi, ti mo ke pe O
Logan l’O dide, ti O pese owo fun mi
Ojojumo n’ipese Re, ninu aye mi
Baba mo wa dupe, fun ‘pese Re igba gbogbo.

3. L’ojo ti ogun dide, ti mo ke pe O
Logan l’O dide, ti O fun mi ni isegun
L’ojo ti Esu nfeju, ti mo ke pe O
Logan l’O dide, ti O pa Esu l’enumo
Ojojumo ni abo Re, ninu aye mi
Baba mo wa dupe, fun abo Re igba gbogbo.