BABA MI ELEDA MI
Composed by Z. A. Ogunsanya, 13/11/2019. In my room, while meditating on my bed in the evening.
1.Baba mi, Eleda mi
Oluwa, Olorun mi
Iwo ni mo gbekele
Ma se je k’oju ti mi.
Egbe: Baba Iwo ni mo gb’ojule
Baba Iwo ni mo f’eyin ti o
Baba Iwo ni mo gbekele
Ma se je k’ipa Esu ka mi.
2. Ni ile ati l’ode
Ati n’irin ajo mi
N’ibikibi ti mo wa
Ma se je k’ewu wu mi.
3. L’oni yi ati l’ola
L’owuro ati l’ale
L’ojo gbogbo l’aye mi
Ma se je k’ibi ba mi.
4. L’oju ona toro yi
Ninu aye elewu
Je k’emi le se’fe Re
Ma se je k’emi subu.
5. Ti mo ba f’aye sile
L’ati lo s’ayeraye
Ka mi ye ni odo Re
Ma se je k’emi segbe.