HYMN – BABA MA JE KI NKUNA

BABA MA JE KI NKUNA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 31/9/2018.

 1. Baba ma je ki nkuna
  Mu k’emi se ife Re
  N’igba gbogbo l’aye mi
  Ati ni ibi gbogbo
  Fun mi ni, ore ofe
  L’ati gboran.

 2. Baba ma je ki nsubu
  Je k’emi duro sinsin
  N’ipo yowu k’emi ba
  Ara mi ninu aye
  Fun mi ni, ore ofe
  L’ati duro.

 3. Baba ma je ki ndese
  Mu ki emi je mimo
  Ninu ero at’ise
  L’ona gbogbo l’aye mi
  Fun mi ni, ore ofe
  Jije mimo.

 4. Baba ma je ki nsaisan
  Mu ki emi n’ilera
  Nipa t’ara at’emi
  N’ibi gbogbo l’aye mi
  Fun mi ni, ore ofe
  Ti ilera.

 5. Baba ma je k’o re mi
  Mu ki emi l’agbara
  Okun ati igboya
  Ni gbogbo oj’aye mi
  Fun mi ni, ore ofe
  L’ati l’okun.

 6. Baba ma je ki ngegun
  Mu ki emi maa sure
  Fun ore at’ota mi
  Ati gbogbo eniyan
  Fun mi ni, ore ofe
  Ti sisure.

 7. Baba fun mi n’igbagbo
  K’emi ma siyemeji
  K’emi le gbekele O
  K’emi si ba Esu ja
  Fun mi ni, ore ofe
  Ti igbagbo.

 8. Baba f’okan mi bale
  Ma se je k’eru ba mi
  Fun mi ni agbara Re
  At’itoju l’atoke
  Fun mi ni, ore ofe
  Ti isimi.