BABA GBE MI RO
Composed by Z. A. Ogunsanya, 21/9/2016.
-
Baba gbe mi ro (Baba mi Mimo)
Fe se mi mule (amin Oluwa)
Ni’pa ‘gbara Emi Mimo
Baba gbe mi ro (amin)
Gbe mi ro, Baba gbe mi ro
Ki nni’gboya. -
Baba di mi mu (Baba agbara)
F’agbara kun mi (amin Oluwa)
Ni’pa ‘gbara t’O se’leri
Baba di mi mu (amin)
Di mi mu, Baba di mi mu
Ki nni okun. -
Baba wo mi san (Baba mi iye)
Fi’lera fun mi (amin Oluwa)
Ni’pa pasan t’a fi na O
Baba wo mi San (amin)
Wo mi san, Baba wo mi san
Ki nsi lera. -
F’ayo Re kun mi (Baba onife)
Le ‘banuje lo (amin Oluwa)
Ni’pa ayo Emi Mimo
F’ayo Re kun mi (amin)
F’i kun mi, F’ayo Re kun mi
Ki nsi ma yo. -
Fun mi ni’simi (Olore-ofe)
Le idamu lo (amin Oluwa)
Ni’pa awon ileri Re
Fun mi ni’simi (amin)
Isimi, Fun mi ni’simi
Ki nma beru. -
Mu mi gba’dura (Baba alanu)
Ma je k’o re mi (amin Oluwa)
Ni’pa ‘gbara Emi Mimo
Mu mi gba’dura (amin)
Adura, Mu mi gba’dura
Ki nsi ri gba. -
Mu mi se’fe Re (Baba ologo)
Ma je ki ndese (amin Oluwa)
Ni’pa iranwo oro Re
Mu mi se’fe Re (amin)
Ife Re, Mu mi se’fe Re
Ki nsi segun.