HYMN – AYERAYE ELEDUMARE OBA OGO

AYERAYE ELEDUMARE OBA OGO
Composed by Z. A. Ogunsanya, 21/8/2019. Early in the morning, while still on my bed.

1. Ayeraye Eledumare Oba ogo
Ayeraye Eleruniyin Alagbara
Oba ana, oni, ola at’ayeraye
Iwo ni mo f’eyin mi ti k’oju ma le ti mi.

Egbe: Oba Eledumare
Apata Ayeraye
Wa ba mi se t’emi
K’o le dara fun mi.

2. Oba t’o mu owo jade l’at’enu eja
Oba t’o mu omi jade ninu apata
Oba t’o ro’jo mana fun ogoji odun
Iwo ni mo f’eyin mi ti k’ebi ma le pa mi.

3. Oba t’o segun Golayati fun Dafidi
Oba t’o p’oro ina fun Heberu meta
Oba t’o di kiniun l’enu fun Daniel
Iwo ni mo f’eyin mi ti k’ota ma bori mi.

4. Oba t’o la’ju afoju t’o m’amukun rin
Oba t’o mu odi fohun t’o m’aditi gbo
Oba t’o l’agbara lati se ohun gbogbo
Iwo ni mo f’eyin mi ti k’arun ma ba le mi.

5. Oba t’o we adete mo ninu ete re
Oba t’o ji oku Lasaru n’ijo kerin
Oba t’o mu ki Peteru rin l’ori okun
Iwo ni mo f’eyin mi ti k’emi ma se kuna.

6. Oba t’o ku t’o tun ji dide n’ijo keta
Oba ti O tun g’oke pada lo si orun
Oba ti yo wa ko wa lo si ile ogo
Iwo ni mo f’eyin mi ti k’emi ma le segbe.