HYMN – ARAYE EGBO (KO S’ALAGBARA BI TI JESU NI GBOGBO AYE)

ARAYE EGBO (KO S’ALAGBARA BI TI JESU NI GBOGBO AYE)
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 1/1/2018. 180101 My first song after the new year eve program.

 1. Araye egbo, (E tete, e tetigbo) otito l’oro yi o
  Ko s’alagbara bi ti Jesu ni gbogbo aye
  Ko s’alagbara bi ti Jesu n’ibi kankan
  Oba t’o nla’ju afoju, t’O nji oku dide
  Oba t’O nm’aro l’arada, t’O nwe adete mo
  Agbara Jesu yi o, ko s’iru re n’ibi kankan.

Egbe: Ko si, ko si rarara, n’ibi kankan.

 1. Araye egbo, (E tete, e tetigbo) otito l’oro yi o
  Ko s’olugbala bi ti Jesu ni gbogbo aye
  Ko s’olugbala bi ti Jesu n’ibi kankan
  Oba t’O ns’omo okunkun di omo imole
  Oba t’O dariji mi, t’O si gba okan mi la
  Igbala Jesu yi o, ko s’iru re n’ibi kankan.
 2. Araye egbo, (E tete, e tetigbo) otito l’oro yi o
  Ko s’olugbeja bi ti Jesu ni gbogbo aye
  Ko s’olugbeja bi ti Jesu n’ibi kankan
  Oba t’O nda onde s’ile l’owo emi Esu
  Oba t’O rin l’ori okun, t’O si ba iji wi
  Igbeja Jesu yi o, ko s’iru re n’ibi kankan.
 3. Araye egbo, (E tete, e tetigbo) otito l’oro yi o
  Ko s’olupe se bi ti Jesu ni gbogbo aye
  Ko s’olupese bi ti Jesu n’ibi kankan
  Oba t’O f’akara marun bo opo eniyan
  Oba t’O npese fun gbogbo aini mi l’aye
  Ipese Jesu yi o, ko s’iru re n’ibi kankan.
 4. Araye egbo, (E tete, e tetigbo) otito l’oro yi o
  Ko s’olutunu bi ti Jesu ni gbogbo aye
  Ko s’olutunu bi ti Jesu n’ibi kankan
  Oba t’O ntu mi n’inu ninu gbogbo wahala
  Oba t’O mu eru mi lo, t’O f’okan mi bale
  Itunu Jesu yi o, ko s’iru re n’ibi kankan.
 5. Araye egbo, (E tete, e tetigbo) otito l’oro yi o
  Ko s’oniyanu bi ti Jesu ni gbogbo aye
  Ko s’oniyanu bi ti Jesu n’ibi kankan
  Oba t’O ku t’O si tun jinde ni ijo keta
  Oba t’O goke lo s’orun ti yo tun pada wa
  Iyanu Jesu yi o, ko s’iru re n’ibi kankan.