HYMN – ALAGBARA NI OLORUN

ALAGBARA Ni OLORUN WA
Composed by Z. A. Ogunsanya, 4/6/2019. In my office.

1. Alagbara ni Olorun wa
Oniyanu ni Olorun wa
Ko si aseti ni odo Re
E je k’a gbekele
K’O le so aye wa d’iyanu.

Egbe: Emi yo gbekele Baba
Emi yo simile d’opin
Emi ba gbelele, ko ni jogun ofo
Emi ti gbekele, oju ko ni ti mi lae lae

2. Olugbala ni Olorun wa
Atunida ni Olorun wa
Ko si eni ti ko le gbala
E je ki a gbagbo
K’O le so aye wa di otun.

3. Olubukun ni Olorun wa
Olupese ni Olorun wa
Ko si aini ni odo Re
E je k’a f’aramo
K’O le ba aini wa pade.

4. Oluwosan ni Olorun wa
Olutunu ni Olorun wa
Ko s’ijakule ni odo Re
E je k’a simile
K’O le ko ijakule wa lo.