HYMN – ALAGBARA NI JESUS (O DAMILOJU)

ALAGBARA NI JESUS (O DAMILOJU)
Composed by Z. A. Ogunsanya, 2/4/2018.

 1. Alagbara ni Jesus (O damiloju)
  Alagbara ni Jesu (O yemiyeke o)
  Oba t’O nrin l’ori okun (t’O nrin l’ori okun)
  Oba t’O nba afefe wi (t’O nba afefe wi)
  Oba t’O p’Esu l’enu mo (t’O p’Esu l’enu mo)
  Oba Onise iyanu (Onise iyanu)
  Agbara Jesu yi o, ko tun s’iru re n’ibi kankan.

Egbe: T’ewe t’agba ni gbogbo agbaye
E sare wa, e wa gba Jesu o
K’O le ba yin se, Yo ba yin se ni aseyori
Ti e ba le wa.

 1. Olugbala ni Jesus (O damiloju)
  Olugbala ni Jesu (O yemiyeke o)
  Oba t’a bi omode (t’a bi omode)
  Oba t’O je opo iya (t’O je opo iya)
  Oba t’O ku t’O ji dide (t’O ku t’O ji dide)
  Oba t’O ngba elese la (t’O ngba elese la)
  Igbala Jesu yi o, ko tun s’iru re n’ibi kankan.

 2. Oluwosan ni Jesus (O damiloju)
  Oluwosan ni Jesu (O yemiyeke o)
  Oba t’O nlaju afoju (t’O nlaju afoju)
  Oba t’O nmarolarada (t’O nmarolarada)
  Oba t’O nwe adete mo (t’O nwe adete mo)
  Oba t’O nji oku dide (t’O nji oku dide)
  Iwosan Jesu yi o, ko tun s’iru re n’ibi kankan.