TE’WO GB’OPE WA, BABA ATOF’ARATI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 6/4/2017.
- Te’wo gb’ope wa, Baba Atof’arati
A wa s’ope o, Baba Awimayehun.
Egbe: A dupe (A dupe)
E se o Baba
Baba E se a dupe.
-
N’ibi gbogbo o, Baba l’O ndabo bo wa
Iranlowo Re, Baba ko ni afiwe. -
N’igba gbogbo o, Baba l’O nse ‘toju wa
L’ona gbogbo o, Baba l’O nduro ti wa. -
L’oju orun wa, Baba ni gbogbo oru
Esu nsa’pa re, Baba O ngbe wa bori. -
N’ibi ise wa, Baba l’ojo gbogbo o
Atileyin Re, Baba nfun wa n’igbega. -
N’irin ajo wa, Baba ‘gbat’ewu ndide
T’a nke pe O o, Baba O un ko wa yo. -
L’ojo isoro, Baba t’ireti wa pin
Oro mimo Re, Baba mu wa l’okan le. -
‘Gba t’ogun ndide, Baba ninu ile wa
Emi Mimo Re, Baba nf’okan wa bale. -
L’ojo ikehin, Baba t’iku ba ti de
Ile ologo, Baba l’a o ba O lo.