ORE MA SOKUN MO
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 27/9/2016.
- Ore ma sokun mo, tete ma an bo
Gbe isoro re, wa s’odo Jesu
Ko s’eni t’o wa, ti Jesu ko yal’enu.
Egbe: Bi Jesu ti se’yi, O le se tire
Ani b’O ti se’yi, ni yo se tire.
Tori bi aye ti ri
Ekun re le pe, di ale kan
Isoro re le gun, fun ojo pipe
Sugbon l’odo Jesu, ireti wa fun o
Amin o, bee ni k’ori, fun mi o.
-
Fun odun mejila, l’onisun-eje
Fi wa iranwo, l’odo eniyan
Sugbon l’ojo kan, ni Jesu tan ‘soro re. -
Lasaru ti o ku, fun ojo merin
‘Gba Jesu de be, t’O gbadura fun
O si ji dide, o f’ayo lo si’le re. -
Adete mewa yen, ti won ri Jesu
L’ehin t’O so’ro, won ye’ra won wo
Won si ri wipe, gbogbo won l’O ti wosan. -
Opo ti Naini, ti omo re ku
O pade Jesu, Jesu f’owo kan
Posi omo na, l’ogan l’o si fo dide. -
Alarun egba ni, ti ko le rin mo
Awon ore gbe, wa s’odo Jesu
B’o si ti de’be, ni Jesu mu l’arada. -
‘Gbati Batimeu, ke’gbe si Jesu
Jesu duro je, O sope k’o wa
L’oju ese ni, O si la oju re fun. -
Akara marun ni, at’eja meji
Jesu sure si, t’O si gbe kale
Egbegberun ni, awon t’o je t’o seku. -
Alarun ti o wa, l’eti adagun
Fun odun meji, din ni ogoji
B’o ti ri Jesu, l’o si gba iwosan re. -
Okunrin Gadara, nibi iboji
Fun opo odun, l’o fi ya were
B’o ti ri Jesu, l’ogan l’o d’ominira.