IWO T’O KU K’EMI LE YE
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 5/1/2016.
Egbe: Iwo t’O ku, (t’O ku) k’emi le ye (le ye)
Iwo t’O j’iya, (j’iya) k’emi ma segbe (rara)
Iwo t’a kan, (t’a kan) mo agbelebu (fun mi)
Oluso–agutan mi, mo dupe o.
-
Judasi omo, eyin Re da O
Nitori ogbon, owo fadaka
Gbogb’ore Re, l’o ko O sile
Olugbala mi, mo dupe o. -
Ejo ebi ni, aye da fun O
B’o tile je pe, Iwo ko d’ese
Won kegan Re, na O ni pasan
Olugbala mi, mo dupe o. -
Ori mimo Re, de ade egun
Owo mimo Re, ni won kan mo’gi
Won tun f’oko, gun O ni egbe
Olugbala mi, mo dupe o. -
Pilatu ati, Herodu pelu
Awon om’ogun, fi O seleya
Lehin t’awon, Ju pa’ro mo O
Olugbala mi, mo dupe o. -
Baba Re l’orun, na ko O si le
Olosa pelu, fi O se yeye
L’ona pupo, l’O jiya fun mi
Olugbala mi, mo dupe o. -
Lehin iku Re, O sokale lo
S’orun apadi, nitori t’emi
O gba koko-ro l’owo Esu
Olugbala mi, mo dupe o. -
Emi ni ebi, yi gbogbo to si
Sugbon nitori, ti Baba fe mi
L’O se fi O, ru’bo f’ese mi
Olugbala mi, mo dupe o. -
Iku ti O ku, O ko ku lasan
Nipase eyi, ni mo ri’gbala
Ti mo si wa, d’omo Olorun
Olugbala mi, mo dupe o. -
Mo ti pinu tan, lati se ‘fe Re
Ni’po ki’po ti, mo ba ba’ra mi
Nko ni gbagbe, iya Re fun mi
Olugbala mi, mo dupe o. -
Ni’le ologo, ni ayeraye
Emi yo dupe, emi yo yin O
Fun ohun nla, ti O se fun mi
Olugbala mi, mo dupe o.